-
1 Àwọn Ọba 15:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Torí náà, Bááṣà ọba Ísírẹ́lì wá dojú kọ Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́* Rámà,+ kí ẹnikẹ́ni má bàa jáde tàbí kí ó wọlé sọ́dọ̀* Ásà ọba Júdà.+ 18 Ni Ásà bá kó gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba, ó sì kó wọn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ọba Ásà wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì ọmọ Tábúrímónì ọmọ Hésíónì, ọba Síríà,+ tó ń gbé ní Damásíkù, ó sọ pé: 19 “Àdéhùn* kan wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín bàbá mi àti bàbá rẹ. Mo fi ẹ̀bùn fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Wò ó, lọ yẹ àdéhùn* tí o bá Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ṣe, kó lè pa dà lẹ́yìn mi.”
-