ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 16:1-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Ásà, Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì wá dojú kọ Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́* Rámà,+ kí ẹnikẹ́ni má bàa jáde tàbí kí ó wọlé sọ́dọ̀* Ásà ọba Júdà.+ 2 Ni Ásà bá kó fàdákà àti wúrà jáde látinú àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì ọba Síríà+ tó ń gbé ní Damásíkù, ó sọ pé: 3 “Àdéhùn* kan wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín bàbá mi àti bàbá rẹ. Mo fi fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Wò ó, lọ yẹ àdéhùn* tí o bá Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ṣe, kó lè pa dà lẹ́yìn mi.”

      4 Bẹni-hádádì ṣe ohun tí Ọba Ásà sọ, ó rán àwọn olórí ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì ṣá Íjónì,+ Dánì + àti Ebẹli-máímù balẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ibi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí ní àwọn ìlú Náfútálì.+ 5 Nígbà tí Bááṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú kíkọ́* Rámà, ó sì pa iṣẹ́ tó ń ṣe níbẹ̀ tì. 6 Ọba Ásà wá kó gbogbo Júdà jọ, wọ́n kó àwọn òkúta àti ẹ̀là gẹdú tó wà ní Rámà,+ tí Bááṣà fi ń kọ́lé,+ ó sì fi wọ́n kọ́* Gébà+ àti Mísípà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́