-
1 Àwọn Ọba 22:42, 43Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 Ẹni ọdún márùndínlógójì (35) ni Jèhóṣáfátì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ásúbà ọmọ Ṣílíháì. 43 Ó ń rìn ní gbogbo ọ̀nà Ásà+ bàbá rẹ̀. Kò yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà.+ Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+
-