8 Gbàrà tí Ásà gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Ódédì, ó mọ́kàn le, ó sì mú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà+ àti Bẹ́ńjámínì àti ní àwọn ìlú tó gbà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó tún pẹpẹ Jèhófà tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà wọ ilé Jèhófà mọ.+