-
2 Kíróníkà 24:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun ará Síríà tó ya wá kò pọ̀, Jèhófà fi ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an lé wọn lọ́wọ́,+ nítorí wọ́n ti fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀; torí náà, wọ́n* mú ìdájọ́ ṣẹ sórí Jèhóáṣì. 25 Nígbà tí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ (nítorí wọ́n fi í sílẹ̀ pẹ̀lú ọgbẹ́ yán-na-yàn-na* lára), àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí ó ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ* àlùfáà Jèhóádà+ sílẹ̀. Wọ́n pa á lórí ibùsùn rẹ̀.+ Bó ṣe kú nìyẹn, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì,+ àmọ́ wọn ò sin ín sí ibi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí.+
-
-
2 Kíróníkà 28:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Níkẹyìn, Áhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ìlú náà, ní Jerúsálẹ́mù, nítorí wọn kò gbé e wá sí ibi tí wọ́n sin àwọn ọba Ísírẹ́lì sí.+ Hẹsikáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
-