-
1 Àwọn Ọba 3:5-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ní Gíbíónì, Jèhófà fara han Sólómọ́nì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì sọ pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+ 6 Ni Sólómọ́nì bá sọ pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì bàbá mi, lọ́nà tó ga, bó ṣe rìn níwájú rẹ ní òtítọ́ àti ní òdodo pẹ̀lú ọkàn tó dúró ṣinṣin. Títí di òní yìí, ò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ kan náà hàn sí i lọ́nà tó ga tí o fi fún un ní ọmọkùnrin kan láti jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀.+ 7 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, o ti fi ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́* ni mí, tí mi ò sì ní ìrírí.*+ 8 Ìránṣẹ́ rẹ wà lára àwọn èèyàn rẹ tí o yàn,+ àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an débi pé wọn ò níye, wọn ò sì ṣeé kà. 9 Torí náà, fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn tó ń gbọ́ràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ,+ láti fi mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú,+ torí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ gan-an* yìí?”
-