-
2 Àwọn Ọba 14:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Nígbà náà, Amasááyà rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pé: “Wá, jẹ́ ká dojú ìjà kọ ara wa.”*+ 9 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Amasááyà ọba Júdà, pé: “Èpò ẹlẹ́gùn-ún tó wà ní Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí igi kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì, pé, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi kó fi ṣe aya.’ Àmọ́, ẹranko kan láti Lẹ́bánónì kọjá, ó sì tẹ èpò ẹlẹ́gùn-ún náà pa. 10 Òótọ́ ni pé o ti ṣẹ́gun Édómù,+ torí bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga fi wọ̀ ẹ́ lẹ́wù. Dúró sí ilé* rẹ, kí o sì jẹ́ kí ògo rẹ máa múnú rẹ dùn. Kí ló dé tí wàá fi fa àjálù bá ara rẹ, tí wàá sì gbé ara rẹ àti Júdà ṣubú?”
-