4 Ni akọgun kan bá jáde láti ibùdó àwọn Filísínì, Gòláyátì ni orúkọ rẹ̀,+ ará Gátì ni,+ gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. 5 Ó dé akoto bàbà sórí, ó sì wọ ẹ̀wù irin tí àwọn ìpẹ́ rẹ̀ gbẹ́nu léra. Ìwọ̀n ẹ̀wù irin bàbà+ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ṣékélì.