ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 14:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Júdà ń ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ wọ́n fi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá mú un bínú ju bí àwọn baba ńlá wọn ṣe mú un bínú lọ.+ 23 Àwọn náà ń kọ́ ibi gíga àti àwọn ọwọ̀n òrìṣà pẹ̀lú àwọn òpó òrìṣà*+ fún ara wọn sórí gbogbo òkè+ àti sábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+

  • 2 Àwọn Ọba 15:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Ní ọdún kejì Pékà ọmọ Remaláyà ọba Ísírẹ́lì, Jótámù+ ọmọ Ùsáyà+ ọba Júdà jọba.

  • 2 Àwọn Ọba 15:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ Òun ló kọ́ ẹnubodè apá òkè tó wà ní ilé Jèhófà.+

  • 2 Kíróníkà 21:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni Jèhórámù nígbà tó jọba, ọdún mẹ́jọ ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+

  • 2 Kíróníkà 21:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Òun náà ṣe àwọn ibi gíga + lórí àwọn òkè Júdà, kí ó lè mú àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ó sì kó Júdà ṣìnà.

  • 2 Kíróníkà 33:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 Ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Mánásè+ nígbà tó jọba, ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+

  • 2 Kíróníkà 33:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ ti wó lulẹ̀,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe àwọn òpó òrìṣà.* Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́