ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 12:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ máa lé kúrò bá ti sin àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ pa run pátápátá,+ ì báà jẹ́ lórí àwọn òkè tó ga tàbí lórí àwọn òkè kéékèèké tàbí lábẹ́ igi èyíkéyìí tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. 3 Kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú,+ kí ẹ dáná sun àwọn òpó òrìṣà* wọn, kí ẹ sì gé ère àwọn ọlọ́run wọn+ tí wọ́n gbẹ́ lulẹ̀, kí orúkọ wọn lè pa rẹ́ kúrò níbẹ̀.+

  • Àìsáyà 57:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti kó sí lórí láàárín àwọn igi ńlá,+

      Lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+

      Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ ní àwọn àfonífojì,+

      Lábẹ́ àwọn pàlàpálá àpáta?

  • Jeremáyà 2:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 ‘Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti ṣẹ́ àjàgà rẹ sí wẹ́wẹ́+

      Mo sì já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ.

      Ṣùgbọ́n, o sọ pé: “Mi ò ní sìn ọ́,”

      Torí pé orí gbogbo òkè àti abẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+

      Ni o nà gbalaja sí, tí ò ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+

  • Hósíà 4:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Orí àwọn òkè ńlá ni wọ́n ti ń rúbọ,+

      Orí àwọn òkè kéékèèké ni wọ́n sì ti ń mú àwọn ẹbọ rú èéfín,

      Lábẹ́ àwọn igi ràgàjì* àti àwọn igi tórásì àti onírúurú igi ńlá,+

      Torí pé ibòji àwọn igi náà dára.

      Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọbìnrin yín fi ń ṣe ìṣekúṣe*

      Tí aya àwọn ọmọ yín sì ń ṣe àgbèrè.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́