ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 4:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 “‘Tí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn+ bá dẹ́ṣẹ̀,+ tó sì mú kí àwọn èèyàn jẹ̀bi, kó mú akọ ọmọ màlúù kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.+

  • Léfítíkù 4:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “‘Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀,+ tí wọ́n sì jẹ̀bi, àmọ́ tí gbogbo ìjọ ò mọ̀ pé àwọn ti ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí wọ́n má ṣe,+ 14 tí wọ́n bá wá mọ̀ pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀, kí ìjọ mú akọ ọmọ màlúù kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì mú un wá síwájú àgọ́ ìpàdé.

  • Nọ́ńbà 15:22-24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 “‘Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ẹ ṣe àṣìṣe, tí ẹ ò sì pa gbogbo àṣẹ yìí tí Jèhófà sọ fún Mósè mọ́, 23 gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún yín nípasẹ̀ Mósè láti ọjọ́ tí Jèhófà ti pàṣẹ àti jálẹ̀ àwọn ìran yín, 24 tó sì jẹ́ pé àṣìṣe ni, tí gbogbo àpéjọ náà ò sì mọ̀, kí gbogbo àpéjọ náà mú akọ ọmọ màlúù kan wá láti fi rú ẹbọ sísun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,+ pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́