29 Nígbà ayé Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà kógun wọ Íjónì, Ebẹli-bẹti-máákà,+ Jánóà, Kédéṣì,+ Hásórì, Gílíádì+ àti Gálílì, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Náfútálì,+ ó sì gbà á, ó wá kó àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Ásíríà.+
26 Nítorí náà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi èrò kan sọ́kàn* Púlì ọba Ásíríà+ (ìyẹn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà), tí ó fi kó àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè lọ sí ìgbèkùn, ó kó wọn wá sí Hálà, Hábórì, Hárà àti odò Gósánì,+ ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní yìí.
20 Níkẹyìn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà wá gbéjà kò ó, ó sì kó ìdààmú bá a+ dípò kó fún un lókun. 21 Áhásì ti kó àwọn nǹkan tó wà ní ilé Jèhófà àti ilé* ọba+ àti ilé àwọn ìjòyè, ó sì fi ṣe ẹ̀bùn fún ọba Ásíríà; àmọ́ kò ṣe é láǹfààní kankan.