-
1 Àwọn Ọba 8:65, 66Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
65 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì ṣe àjọyọ̀+ náà pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ ìjọ ńlá láti Lebo-hámátì* títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ wọ́n wà níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa fún ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje míì, ó jẹ́ ọjọ́ mẹ́rìnlá (14) lápapọ̀. 66 Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e,* ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn, ayọ̀ sì kún ọkàn wọn nítorí gbogbo oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀.
-