16 Lẹ́yìn náà, Jèhóádà dá májẹ̀mú láàárín òun àti gbogbo àwọn èèyàn náà àti ọba pé àwọn á máa jẹ́ èèyàn Jèhófà nìṣó.+ 17 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn èèyàn náà wá sí ilé Báálì, wọ́n sì wó o lulẹ̀,+ wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ rẹ̀ àti àwọn ère rẹ̀ túútúú,+ wọ́n sì pa Mátánì àlùfáà Báálì+ níwájú àwọn pẹpẹ náà.