30Hẹsikáyà ránṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì+ àti Júdà, ó tiẹ̀ tún kọ lẹ́tà sí Éfúrémù àti Mánásè,+ pé kí wọ́n wá sí ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe Ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
18 Nítorí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà, pàápàá àwọn tó wá láti Éfúrémù, Mánásè,+ Ísákà àti Sébúlúnì ni kò tíì wẹ ara wọn mọ́, síbẹ̀ wọ́n jẹ Ìrékọjá, èyí sì ta ko ohun tó wà lákọsílẹ̀. Àmọ́ Hẹsikáyà gbàdúrà fún wọn pé: “Kí Jèhófà, ẹni rere,+ dárí ji