11 “Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì ti jẹ́ kí inú tó ń bí mi sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rọlẹ̀ torí pé kò fàyè gba bíbá mi díje rárá láàárín wọn.+ Ìdí nìyẹn ti mi ò fi pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún wọn pé èmi nìkan ṣoṣo ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa sìn.+
28 Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì, ọmọ Áárónì, ló ń ṣiṣẹ́* níwájú rẹ̀ nígbà yẹn. Wọ́n béèrè pé: “Ṣé ká tún lọ bá àwọn arákùnrin wa, àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì jà, àbí ká má lọ mọ́?”+ Jèhófà fèsì pé: “Ẹ lọ, torí ọ̀la ni màá fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”