-
Ẹ́sírà 6:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ohunkóhun tí wọ́n bá nílò, látorí àwọn ọmọ akọ màlúù,+ àwọn àgbò+ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn + fún àwọn ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, dórí àlìkámà,*+ iyọ̀,+ wáìnì+ àti òróró,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe sọ, gbogbo rẹ̀ ni kí ẹ máa fún wọn lójoojúmọ́, kò gbọ́dọ̀ yẹ̀, 10 kí wọ́n lè máa mú ọrẹ tó ń mú inú Ọlọ́run ọ̀run dùn wá déédéé, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún ẹ̀mí ọba àti ti àwọn ọmọ rẹ̀.+
-