9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrú ni wá,+ Ọlọ́run wa kò fi wá sílẹ̀ nínú ipò ẹrú tí a wà; àmọ́ ó ti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa níwájú àwọn ọba Páṣíà,+ láti gbé wa dìde kí a lè kọ́ ilé Ọlọ́run wa,+ kí a sì tún àwọn ibi tó ti di àwókù ṣe, kí ó sì fún wa ní odi ààbò* ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù.
11 Ìwọ Jèhófà, jọ̀ọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí inú wọn ń dùn láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ, jọ̀ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ ṣàṣeyọrí lónìí, kí ọkùnrin yìí sì ṣojú àánú sí mi.”+