22 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń dá gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá.+ Wọn kò jáwọ́ nínú wọn 23 títí Jèhófà fi mú Ísírẹ́lì kúrò níwájú rẹ̀, bó ṣe sọ látẹnu gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.+ Bí wọ́n ṣe kó Ísírẹ́lì nígbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ lọ sí Ásíríà+ nìyẹn, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.
6 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́. 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+