-
Ẹ́sírà 9:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Bí mo ṣe gbọ́ nípa nǹkan yìí, mo fa ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá ya, mo fa lára irun orí mi àti irùngbọ̀n mi tu, mo jókòó, kàyéfì ńlá sì ń ṣe mí. 4 Nígbà náà, gbogbo àwọn tó ní ọ̀wọ̀ fún* ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ mi nítorí ìwà àìṣòótọ́ àwọn tó dé láti ìgbèkùn, mo wà ní ìjókòó, kàyéfì ńlá sì ń ṣe mí títí di ìgbà ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́.+
-
-
Dáníẹ́lì 9:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Mo wá yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, mo bẹ̀ ẹ́ bí mo ṣe ń gbàdúrà sí i, pẹ̀lú ààwẹ̀,+ aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú. 4 Mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run mi, mo jẹ́wọ́, mo sì sọ pé:
“Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, tó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ 5 a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe ohun tí kò dáa, a ti hùwà burúkú, a sì ti ṣọ̀tẹ̀;+ a ti kọ àwọn àṣẹ rẹ àti àwọn ìdájọ́ rẹ sílẹ̀.
-