-
1 Kíróníkà 29:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 wúrà fún iṣẹ́ ọnà wúrà àti fàdákà fún iṣẹ́ ọnà fàdákà àti fún gbogbo iṣẹ́ tí àwọn oníṣẹ́ ọnà máa ṣe. Ní báyìí, ta ló fẹ́ mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà lónìí?”+
-
-
Nehemáyà 7:70-72Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
70 Lára àwọn olórí agbo ilé mú ọrẹ wá fún iṣẹ́ náà.+ Gómìnà* mú ẹgbẹ̀rún kan (1,000) owó dírákímà* wúrà, àádọ́ta (50) abọ́ àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ọgbọ̀n (530) aṣọ àwọn àlùfáà+ wá sí ibi ìṣúra. 71 Lára àwọn olórí agbo ilé mú ọ̀kẹ́ kan (20,000) owó dírákímà wúrà àti ẹgbẹ̀rún méjì ó lé igba (2,200) mínà* fàdákà wá sí ibi ìṣúra iṣẹ́ ilé náà. 72 Àwọn èèyàn yòókù sì mú ọ̀kẹ́ kan (20,000) owó dírákímà wúrà àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) mínà fàdákà àti àádọ́rin dín mẹ́ta (67) aṣọ àwọn àlùfáà wá.
-