-
Nehemáyà 6:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Mo wá lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà ọmọ Méhétábélì nígbà tó wà ní àhámọ́ níbẹ̀. Ó sọ fún mi pé: “Jẹ́ ká dá ìgbà tí a jọ máa pàdé ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, nínú tẹ́ńpìlì, ká sì ti àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì, nítorí wọ́n ń bọ̀ wá pa ọ́. Òru ni wọ́n máa wá pa ọ́.” 11 Àmọ́ mo sọ pé: “Ṣé irú mi ló yẹ kó sá lọ? Ṣé irú mi lè wọnú tẹ́ńpìlì, kí n má sì kú?+ Mi ò ní wọ ibẹ̀!” 12 Ìgbà náà ni mo rí i pé, kì í ṣe Ọlọ́run ló rán an, Tòbáyà àti Sáńbálátì+ ló lọ gbà á pé kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sí mi.
-