-
2 Kíróníkà 26:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Wọ́n kojú Ọba Ùsáyà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ùsáyà, kò tọ́ sí ọ láti sun tùràrí sí Jèhófà!+ Àwọn àlùfáà nìkan ló yẹ kó máa sun tùràrí, torí àwọn ni àtọmọdọ́mọ Áárónì,+ àwọn tí a ti yà sí mímọ́. Jáde kúrò ní ibi mímọ́, nítorí o ti hùwà àìṣòótọ́, o ò sì ní rí ògo kankan gbà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nítorí èyí.”
19 Àmọ́ inú bí Ùsáyà nígbà tí àwo tó fẹ́ fi sun tùràrí ti wà lọ́wọ́ rẹ̀;+ bí inú ṣe ń bí i sí àwọn àlùfáà lọ́wọ́, ẹ̀tẹ̀+ yọ níwájú orí rẹ̀ níṣojú àwọn àlùfáà nínú ilé Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tùràrí.
-