19 Nígbà tí Sáńbálátì ará Hórónì àti Tòbáyà + ọmọ Ámónì+ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ọba* pẹ̀lú Géṣémù ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi wá ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n sì ń fojú pa wá rẹ́, wọ́n ní: “Kí lẹ̀ ń ṣe yìí? Ẹ fẹ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ọba, àbí?”+
7 Nígbà tí Sáńbálátì, Tòbáyà,+ àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ àti àwọn ọmọ Ámónì pẹ̀lú àwọn ará Áṣídódì+ gbọ́ pé àtúnṣe ògiri Jerúsálẹ́mù ń lọ déédéé àti pé a ti ń dí àwọn àlàfo rẹ̀, inú bí wọn gidigidi.