ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 24:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhóákínì ọba Júdà jáde lọ bá ọba Bábílónì,+ òun àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀;+ ọba Bábílónì sì mú un lẹ́rú ní ọdún kẹjọ ìṣàkóso rẹ̀.+

  • 2 Àwọn Ọba 24:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ó kó gbogbo Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn, gbogbo ìjòyè,+ gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú gbogbo oníṣẹ́ irin,*+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kó lọ sí ìgbèkùn. Kò ṣẹ́ ku ẹnì kankan àfi àwọn aláìní ní ilẹ̀ náà.+

  • 2 Kíróníkà 36:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+

  • 2 Kíróníkà 36:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ó mú àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà lẹ́rú, ó kó wọn lọ sí Bábílónì,+ wọ́n sì di ìránṣẹ́ òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí di ìgbà tí ìjọba* Páṣíà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso,+

  • Jeremáyà 39:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì àti àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó ṣẹ́ kù.

  • Jeremáyà 52:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ sì kó àwọn kan lára àwọn aláìní nínú àwọn èèyàn náà àti àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìlú náà lọ sí ìgbèkùn. Ó tún kó àwọn tó sá lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì àti ìyókù àwọn àgbà oníṣẹ́ ọnà lọ sí ìgbèkùn.+

  • Jeremáyà 52:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Àwọn èèyàn tí Nebukadinésárì* kó lọ sí ìgbèkùn nìyí: ní ọdún keje, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (3,023) àwọn Júù.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́