8Gbogbo àwọn èèyàn náà kóra jọ ní ìṣọ̀kan sí gbàgede ìlú tó wà níwájú Ẹnubodè Omi,+ wọ́n sì sọ fún Ẹ́sírà+ adàwékọ* pé kó mú ìwé Òfin Mósè+ wá, èyí tí Jèhófà pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.+
3 Ó sì kà á sókè+ ní gbàgede ìlú tó wà níwájú Ẹnubodè Omi, láti àfẹ̀mọ́jú títí di ọ̀sán gangan, fún àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà lè yé; gbogbo àwọn èèyàn náà sì fetí sílẹ̀ dáadáa+ sí ìwé Òfin náà.