-
Diutarónómì 16:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ. 15 Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe àjọyọ̀+ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà bá yàn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo ohun tí o bá kórè àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+ wàá sì máa láyọ̀ nígbà gbogbo.+
-