33 Ogójì (40) ọdún+ ni àwọn ọmọ yín fi máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú aginjù, wọ́n sì máa jìyà ìwà àìṣòótọ́ tí ẹ hù* títí ẹni tó kẹ́yìn nínú yín fi máa kú sínú aginjù.+
7 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o ṣe. Ó mọ gbogbo bí o ṣe ń rìn nínú aginjù tó tóbi yìí dáadáa. Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà pẹ̀lú rẹ jálẹ̀ ogójì (40) ọdún yìí, o ò sì ṣaláìní ohunkóhun.”’+