-
Nọ́ńbà 14:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Inú aginjù yìí lẹ máa kú sí,+ àní gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè nínú yín, àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi.+ 30 Ìkankan nínú yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo búra* pé ẹ máa gbé,+ àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọ Núnì.+
31 “‘“Àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé wọ́n máa kó+ lẹ́rú ni màá mú débẹ̀, wọ́n á sì mọ ilẹ̀ tí ẹ kọ̀+ náà.
-