13 Mo gba Ẹnubodè Àfonífojì+ jáde ní òru, mo kọjá níwájú Ojúsun Ejò Ńlá lọ sí Ẹnubodè Òkìtì Eérú,+ mo sì ṣàyẹ̀wò àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù tó ti wó lulẹ̀ àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí iná ti jó.+
13 Hánúnì àti àwọn tó ń gbé ní Sánóà+ tún Ẹnubodè Àfonífojì ṣe;+ wọ́n kọ́ ọ, wọ́n gbé ilẹ̀kùn rẹ̀ sí i àti àwọn ìkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, wọ́n ṣàtúnṣe ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́* lára ògiri náà títí dé Ẹnubodè Òkìtì Eérú.+