8 Hámánì wá sọ fún Ọba Ahasuérúsì pé: “Àwọn èèyàn kan wà káàkiri tí wọ́n ń dá tiwọn ṣe láàárín àwọn èèyàn+ tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀* tó wà lábẹ́ àkóso rẹ,+ òfin wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn èèyàn yòókù; wọn kì í sì í pa òfin ọba mọ́, wọ́n á pa ọba lára tí a bá fi wọ́n sílẹ̀ bẹ́ẹ̀.
24 Hámánì+ ọmọ Hamédátà, ọmọ Ágágì,+ ọ̀tá gbogbo àwọn Júù ti gbèrò láti pa àwọn Júù run,+ ó ti ṣẹ́ Púrì,+ ìyẹn Kèké, láti kó ìpayà bá wọn, kí ó sì pa wọ́n run.