3 Kí ọba yan àwọn kọmíṣọ́nnà ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀+ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó jẹ́ wúńdíá arẹwà jọ sí Ṣúṣánì ilé ńlá, ní ilé àwọn obìnrin. Kí a fi wọ́n sábẹ́ àbójútó Hégáì+ ìwẹ̀fà ọba, olùtọ́jú àwọn obìnrin, kí wọ́n sì máa gba ìtọ́jú aṣaralóge.