7 Nítorí náà, Ọba Ahasuérúsì sọ fún Ẹ́sítà Ayaba àti Módékáì tó jẹ́ Júù pé: “Ẹ wò ó! Mo ti fún Ẹ́sítà ní ilé Hámánì,+ mo sì ti ní kí wọ́n gbé e kọ́ sórí òpó igi,+ nítorí ète tó pa láti gbéjà ko* àwọn Júù.
24 Hámánì+ ọmọ Hamédátà, ọmọ Ágágì,+ ọ̀tá gbogbo àwọn Júù ti gbèrò láti pa àwọn Júù run,+ ó ti ṣẹ́ Púrì,+ ìyẹn Kèké, láti kó ìpayà bá wọn, kí ó sì pa wọ́n run.