16 “Lọ, kó gbogbo àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀+ nítorí mi. Ẹ má jẹ, ẹ má sì mu fún ọjọ́ mẹ́ta,+ ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi á sì gbààwẹ̀ bákan náà. Màá wọlé lọ sọ́dọ̀ ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bá òfin mu, tí mo bá sì máa kú, kí n kú.”