4 Lẹ́yìn náà, ọba sọ pé: “Ta ló wà ní àgbàlá?” Ní àkókò yìí, Hámánì ti dé sí àgbàlá ìta+ ilé* ọba láti sọ fún ọba bí wọ́n ṣe máa gbé Módékáì kọ́ sórí òpó igi tó ti ṣe fún un.+
9 Hábónà,+ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba wá sọ pé: “Hámánì tún ṣe òpó igi kan fún Módékáì,+ ẹni tó sọ ohun tó gba ọba sílẹ̀.+ Òpó náà wà ní òró ní ilé Hámánì, àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́* ni gíga rẹ̀.” Ni ọba bá sọ pé: “Ẹ gbé e kọ́ sórí rẹ̀.”