6 Élíhù ọmọ Bárákélì ọmọ Búsì wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó ní:
“Ọmọdé ni mí,
Àgbàlagbà sì ni ẹ̀yin.+
Ìdí nìyẹn tí mi ò fi sọ̀rọ̀ torí mo bọ̀wọ̀ fún yín,+
Mi ò sì jẹ́ sọ ohun tí mo mọ̀ fún yín.
7 Mo ronú pé, ‘Kí ọjọ́ orí sọ̀rọ̀,
Kí ọ̀pọ̀ ọdún sì kéde ìmọ̀.’