5 Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn máa kú,+ àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá,+ wọn kò sì ní èrè kankan mọ́, nítorí pé wọ́n ti di ẹni ìgbàgbé.+ 6 Bákan náà, ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn pẹ̀lú owú wọn ti ṣègbé, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ nínú ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.+