22 Bákan náà ni gbogbo rẹ̀ rí. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé,
‘Bó ṣe ń pa aláìṣẹ̀ run ló ń pa ẹni burúkú run.’
23 Bí omi tó ya lójijì bá fa ikú òjijì,
Ó máa fi aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó ń dààmú.
24 A ti fi ayé lé ẹni burúkú lọ́wọ́;+
Ó ń bo ojú àwọn adájọ́ rẹ̀.
Tí kì í bá ṣe òun, ta wá ni?