10 Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa,+
Kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.+
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé,
Bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga.+
12 Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,
Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.+