-
Òwe 3:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni àwọn ibú omi fi pínyà
Tí ìkùukùu ojú sánmà sì ń mú kí ìrì sẹ̀.+
-
-
Àìsáyà 55:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí bí òjò àti yìnyín ṣe ń rọ̀ láti ọ̀run gẹ́lẹ́,
Tí kì í sì í pa dà síbẹ̀, àfi tó bá mú kí ilẹ̀ rin, tó jẹ́ kó méso jáde, kí nǹkan sì hù,
Tó jẹ́ kí ẹni tó fúnrúgbìn ká irúgbìn, tí ẹni tó ń jẹun sì rí oúnjẹ,
-
Jeremáyà 14:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Ǹjẹ́ ìkankan lára àwọn òrìṣà lásánlàsàn tí àwọn orílẹ̀-èdè ń bọ lè rọ òjò,
Àbí ṣé ọ̀run fúnra rẹ̀ pàápàá lè dá rọ ọ̀wààrà òjò?
Ìwọ nìkan lo lè ṣe é, Jèhófà Ọlọ́run wa.+
A sì ní ìrètí nínú rẹ,
Nítorí ìwọ nìkan ló ń ṣe gbogbo nǹkan yìí.
-
-
-