1 Àwọn Ọba 18:45 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 45 Láàárín àkókò yìí, ojú ọ̀run ṣú dẹ̀dẹ̀, atẹ́gùn fẹ́, òjò ńlá sì rọ̀;+ Áhábù gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sí Jésírẹ́lì.+ Jóòbù 36:29 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 29 Ṣé ẹnikẹ́ni lè lóye àwọn ìpele ìkùukùu,*Ààrá tó ń sán láti àgọ́* rẹ̀?+ Jóòbù 36:31 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 31 Ó ń fi èyí bójú tó* àwọn èèyàn;Ó ń fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ.+ Jóòbù 38:25-27 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 Ta ló la ọ̀nà fún àkúnya omi,Tó sì la ọ̀nà fún ìjì tó ń sán ààrá látojú ọ̀run,+26 Kí òjò lè rọ̀ síbi tí èèyàn kankan ò gbé,Sí aginjù níbi tí kò sí èèyàn kankan,+27 Kó lè tẹ́ ilẹ̀ tó ti di ahoro lọ́rùn,Kó sì mú kí koríko hù?+ Jémíìsì 5:17, 18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa ni Èlíjà, síbẹ̀, nígbà tó gbàdúrà taratara pé kí òjò má rọ̀, òjò ò rọ̀ sórí ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà.+ 18 Ó tún gbàdúrà, òjò sì rọ̀ láti ọ̀run, ilẹ̀ wá mú èso jáde.+
45 Láàárín àkókò yìí, ojú ọ̀run ṣú dẹ̀dẹ̀, atẹ́gùn fẹ́, òjò ńlá sì rọ̀;+ Áhábù gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sí Jésírẹ́lì.+
25 Ta ló la ọ̀nà fún àkúnya omi,Tó sì la ọ̀nà fún ìjì tó ń sán ààrá látojú ọ̀run,+26 Kí òjò lè rọ̀ síbi tí èèyàn kankan ò gbé,Sí aginjù níbi tí kò sí èèyàn kankan,+27 Kó lè tẹ́ ilẹ̀ tó ti di ahoro lọ́rùn,Kó sì mú kí koríko hù?+
17 Ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa ni Èlíjà, síbẹ̀, nígbà tó gbàdúrà taratara pé kí òjò má rọ̀, òjò ò rọ̀ sórí ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà.+ 18 Ó tún gbàdúrà, òjò sì rọ̀ láti ọ̀run, ilẹ̀ wá mú èso jáde.+