25 Nígbà náà, Jésù sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé.+
16 Bí ẹ ṣe ń ṣe sí ara yín ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹlòmíì; ẹ má ṣe máa ronú nípa àwọn ohun ńláńlá,* àmọ́ ẹ máa ronú nípa àwọn ohun tó rẹlẹ̀.+ Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín.+
26 Nítorí ẹ rí bó ṣe pè yín, ẹ̀yin ará, pé kì í ṣe ọ̀pọ̀ ọlọ́gbọ́n nípa ti ara* ni a pè,+ kì í ṣe ọ̀pọ̀ alágbára, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tí a bí ní ilé ọlá,*+