-
Jóòbù 21:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Ọlọ́run máa fi ìyà èèyàn pa mọ́ de àwọn ọmọ rẹ̀;
Àmọ́ kí Ọlọ́run san án lẹ́san, kó bàa lè mọ̀ ọ́n.+
20 Kó fi ojú ara rẹ̀ rí ìparun rẹ̀,
Kí òun fúnra rẹ̀ sì mu nínú ìbínú Olódùmarè.+
-
Jeremáyà 25:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ fún mi nìyí: “Gba ife wáìnì ìbínú yìí ní ọwọ́ mi, kí o sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá rán ọ sí mu ún.
-
-
Jeremáyà 25:28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Bí wọn ò bá sì gba ife náà lọ́wọ́ rẹ láti mu ún, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ẹ gbọ́dọ̀ mu ún!
-
-
Jeremáyà 49:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó! Bí àwọn tí kò jẹ̀bi láti mu ife náà bá ní láti mu ún ní dandan, ṣé ó wá yẹ kí a fi ọ́ sílẹ̀ láìjìyà? A ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láìjìyà, nítorí o gbọ́dọ̀ mu ún.”+
-
-
Ìfihàn 14:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Áńgẹ́lì kẹta tẹ̀ lé wọn, ó sì ń fi ohùn tó dún ketekete sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá jọ́sìn ẹranko náà+ àti ère rẹ̀, tó sì gba àmì kan sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀,+ 10 òun náà máa mu nínú wáìnì ìbínú Ọlọ́run tó tú jáde láìní àbùlà sínú ife ìbínú Rẹ̀,+ a sì máa fi iná àti imí ọjọ́+ dá a lóró níwájú àwọn áńgẹ́lì mímọ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.
-
-
-