ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 9:18-20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbéjà kò wọ́n, torí pé àwọn ìjòyè àpéjọ náà ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra+ fún wọn. Gbogbo àpéjọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí àwọn ìjòyè náà. 19 Ni gbogbo àwọn ìjòyè náà bá sọ fún gbogbo àpéjọ náà pé: “A ò lè pa wọ́n lára torí pé a ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún wọn. 20 Ohun tí a máa ṣe nìyí: A máa dá ẹ̀mí wọn sí, kí ìbínú má bàa wá sórí wa torí ìbúra tí a ṣe fún wọn.”+

  • Àwọn Onídàájọ́ 11:34, 35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Níkẹyìn, Jẹ́fútà dé sí ilé rẹ̀ ní Mísípà,+ wò ó! ọmọbìnrin rẹ̀ ló ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀, ó ń lu ìlù tanboríìnì, ó sì ń jó! Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Kò ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin míì. 35 Nígbà tó rí i, ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Áà, ọmọbìnrin mi! O ti mú kí ọkàn mi bà jẹ́,* torí ìwọ ni ẹni tí màá ní kó lọ. Mo ti la ẹnu mi sí Jèhófà, mi ò sì lè yí i pa dà.”+

  • Sáàmù 50:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,+

      Kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ;+

  • Mátíù 5:33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 “Ẹ tún gbọ́ pé a sọ fún àwọn èèyàn àtijọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ búra láìṣe é,+ àmọ́ o gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́