17 Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú síbi ẹsẹ̀ rẹ̀ bíi pé mo ti kú.
Ó gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó sì sọ pé: “Má bẹ̀rù. Èmi ni Ẹni Àkọ́kọ́+ àti Ẹni Ìkẹyìn+ 18 àti alààyè,+ mo ti kú tẹ́lẹ̀,+ àmọ́ wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé,+ mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Isà Òkú.+