Jóòbù 33:28 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 28 Ó ti ra ọkàn* mi pa dà kó má bàa lọ sínú kòtò,*+Ẹ̀mí mi sì máa rí ìmọ́lẹ̀.’ Sáàmù 16:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Torí o ò ní fi mí sílẹ̀* nínú Isà Òkú.*+ O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.*+ Sáàmù 30:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Jèhófà, o ti gbé mi* sókè látinú Isà Òkú.*+ O mú kí n wà láàyè, o ò sì jẹ́ kí n rì sínú kòtò.*+ Sáàmù 86:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí mi pọ̀,O sì ti gba ẹ̀mí* mi lọ́wọ́ Isà Òkú.*+