12 Tí ẹni náà bá sì jẹ́ aláìní, ohun tó fi ṣe ìdúró ò gbọ́dọ̀ sun ọ̀dọ̀ rẹ mọ́jú.+13 Gbàrà tí oòrùn bá wọ̀ ni kí o rí i pé o dá ohun tó fi ṣe ìdúró pa dà fún un, kó lè rí aṣọ fi sùn,+ á sì súre fún ọ; èyí á sì jẹ́ òdodo lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
10 Torí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ + bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.