-
Mátíù 21:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Wọ́n mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà àti ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí wọn, ó sì jókòó sórí wọn.+ 8 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èrò náà tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà,+ àwọn míì ń gé àwọn ẹ̀ka igi, wọ́n sì ń tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. 9 Bákan náà, àwọn èrò tó ń lọ níwájú rẹ̀ àti àwọn tó ń tẹ̀ lé e ń kígbe ṣáá pé: “A bẹ̀ ọ́, gba Ọmọ Dáfídì là!+ Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!*+ A bẹ̀ ọ́, gbà á là, ní ibi gíga lókè!”+
-
-
Máàkù 11:7-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ náà wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí rẹ̀, ó sì jókòó sórí rẹ̀.+ 8 Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà, àmọ́ àwọn míì gé àwọn ẹ̀ka igi tó ní ewé látinú pápá.+ 9 Àwọn tó ń lọ níwájú àti àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn sì ń kígbe ṣáá pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là!+ Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!*+ 10 Ìbùkún ni fún Ìjọba Dáfídì bàbá wa tó ń bọ̀!+ A bẹ̀ ọ́, gbà là, ní ibi gíga lókè!”
-
-
Lúùkù 19:37, 38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Gbàrà tó dé tòsí ojú ọ̀nà tó lọ sísàlẹ̀ láti Òkè Ólífì, inú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dùn, wọ́n sì gbóhùn sókè, wọ́n ń yin Ọlọ́run torí gbogbo iṣẹ́ agbára tí wọ́n ti rí, 38 wọ́n ń sọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!* Àlàáfíà ní ọ̀run àti ògo ní ibi gíga lókè!”+
-