ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nehemáyà 4:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Gbọ́, ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí wọ́n ń kàn wá lábùkù,+ dá ẹ̀gàn wọn pa dà sórí wọn,+ jẹ́ kí wọ́n dà bí ẹrù ogun, kí wọ́n sì di ẹrú ní ilẹ̀ àjèjì.

  • Nehemáyà 6:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Nítorí náà, ọjọ́ méjìléláàádọ́ta (52) la fi mọ ògiri náà, ó sì parí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Élúlì.*

      16 Nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá wa gbọ́, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wa ká sì rí i, ìtìjú ńlá* bá wọn,+ wọ́n sì rí i pé Ọlọ́run wa ló ràn wá lọ́wọ́ tí a fi lè parí iṣẹ́ náà.

  • Ẹ́sítà 6:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Hámánì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fún Séréṣì+ aya rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nígbà náà, àwọn amòye rẹ̀ àti Séréṣì aya rẹ̀ sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ* Júù ni Módékáì tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣubú níwájú rẹ̀ yìí, á jẹ́ pé o ò ní borí rẹ̀; ó sì dájú pé wàá ṣubú níwájú rẹ̀.”

  • Ẹ́sítà 9:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Àwọn Júù fi idà ṣá gbogbo àwọn ọ̀tá wọn balẹ̀, wọ́n ń pa wọ́n, wọ́n sì ń run wọ́n; wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n sí àwọn tó kórìíra wọn.+

  • Sáàmù 137:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà, jọ̀wọ́ rántí

      Ohun tí àwọn ọmọ Édómù sọ lọ́jọ́ tí Jerúsálẹ́mù ṣubú, wọ́n ní:

      “Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”+

  • Sekaráyà 12:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di òkúta tó wúwo* fún gbogbo èèyàn. Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá gbé e máa fara pa yánnayànna;+ gbogbo orílẹ̀-èdè ayé sì máa kóra jọ láti gbéjà kò ó.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́