17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé wá láti òkè,+ ó ń wá látọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,+ ẹni tí kì í yí pa dà, tí kì í sì í sún kiri bí òjìji.*+
9 Àmọ́ ẹ̀yin ni “àwọn èèyàn tí Ọlọ́run yàn, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́,+ àwùjọ àwọn èèyàn tó jẹ́ ohun ìní pàtàkì,+ kí ẹ lè kéde káàkiri àwọn ọlá ńlá”*+ Ẹni tó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.+